2 Sámúẹ́lì 20 BMY

Ìṣọ̀tẹ̀ Sí Dáfídì.

1 Ọkùnrin Bélíálì kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣébà ọmọ Bíkírì ará Bẹ́ńjámínì; ó sì fún ìpè ó sì wí pé,“Àwa kò ní ipa nínú Dáfídì,bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jésè!Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Ísírẹ́lì!”

2 Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì lọ kúrò lẹ́yìn Dáfídì, wọ́n sì ń tọ́ Ṣébà ọmọ Bíkírì lẹ́yìn: ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Júdà sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jódánì wá títí ó fi dé Jérúsálẹ́mù.

3 Dáfídì sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ile, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì ṣé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó.

Jóábù Fi Idà Gún Ámásà, Ó Sì Kú.

4 Ọba sì wí fún Ámásà pé, “Pè àwọn ọkùnrin Júdà fún mi níwọn ijọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìnyìí.”

5 Ámásà sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Júdà; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un.

6 Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, “Nísinsinyìí Ṣébè ọmọ Bíkírì yóò ṣe wá ní ibi ju ti Ábúsálómù lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má baà rí ìlú olódì wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.”

7 Àwọn ọmọkùnrin Jóábù sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára: wọ́n sì ti Jérúsálẹ́mù jáde lọ, láti lépa Ṣábà ọmọ Bíkírì.

8 Nígbà tí wọ́n dé ibi òkútà ńlá tí ó wà ní Gíbíónì, Ámásà sì ṣáájú wọn, Jóábù sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.

9 Jóábù sì bi Ámásà léèrè pé, “Ara rẹ kò le bí, ìwọ arákùnrin mi?” Jóábù sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Ámásà ní irungbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

10 Ṣùgbọ́n Ámásà kò sì kíyèsí idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Jóábù: bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́: ó sì kú. Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì.

Jóábù Lépa Ṣébà.

11 Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Jóábù sì dúró tì í, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Jóábù? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dáfídì, kí ó máa tọ Jóábù lẹ́yìn.”

12 Ámásà sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì ríi pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú ìgbẹ́, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró.

13 Nígbà tí ó sì gbé e kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Jóábù lẹ́yìn láti lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì.

Wọ́n Gé Ṣébà Lórí.

14 Ó kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sí Ábélì ti Bẹti Máákà, àti gbogbo àwọn ará Bérítì; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú.

15 Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì í ní Ábélì tí Bẹti Máákà, wọ́n sì mọ odí ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Jóábù sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀.

16 Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹsọ fún Jóábù pé: Súnmọ́ ìhìnyìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.”

17 Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Jóábù bí?”Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.”Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́-bìnrin rẹ.”Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.”

18 Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Níti bíbéèrè, wọn ó béèrè ní Ábélì’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà.

19 Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti tòótọ́ ní Ísírẹ́lì: ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Ísírẹ́lì: èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.”

20 Jóábù sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun.

21 Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Éfúráímù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣébà, ọmọ Bíkírì, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sòkè sí ọba, àní sí Dáfídì: fi òun nìkanṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.”Obìnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odì wá.”

22 Obìnrin náà sì mú ìmọ́ran rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣébà ọmọ Bíkírì lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Jóábù. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká sọ́dọ̀ ọba.

23 Jóábù sì ni olórí gbogbo ogun Ísírẹ́lì: Bénáyà ọmọ Jéhóiádà sì jẹ́ olórí àwọn Kérétì, àti ti àwọn Pélétì.

24 Ádórámù sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde: Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.

25 Ṣéfà sì jẹ́ akọ̀wé: Sádókù àti Ábíátarì sì ni àwọn àlùfáà.

26 Írà pẹ̀lú, ará Jáírì ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dáfídì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24