2 Sámúẹ́lì 18 BMY

Wọ́n Pàdé Ogun Ní Igbó Éfúráímù.

1 Dáfídì sì ka àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì mú wọn jẹ balógun ẹgbẹgbẹ̀rún, àti balógun ọrọrún lórí wọn.

2 Dáfídì sì fi ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn náà lé Jóábù lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ, àti ìdámẹ́ta lé Ábíṣáì ọmọ Serúíà àbúrò Jóábù lọ́wọ́ àti ìdàmẹ́ta lè Ítaì ará Gítì lọ́wọ́, Ọba sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Nítòótọ́ èmi tìkárami yóò sì bá yín lọ pẹ̀lú.”

3 Àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ìwọ kì yóò bá wa lọ: nítorí pé bí àwa bá sá, wọn kì yóò náání wa, tàbí bí ó tílẹ̀ ṣe pé ìdajì wa kú, wọn kì yóò násní wa, nítorí pé ìwọ nìkan tó ẹgbàarún wa: nítorí náà, ó sì dára kí ìwọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti ìlú wá.”

4 Ọba sì wí fún wọn pé, “Èyí tí ó bá tọ́ lójú yin ni èmi ó ṣe.”Ọba sì dúró ní apákan ẹnu odi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde ní ọrọrún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún.

5 Ọba sì pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítaì pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Ábúsálómù.

6 Àwọn ènìyàn náà sì jáde láti pàdé Ísírẹ́lì ní pápá; ní igbó Éfúráímù ni wọ́n gbé pàdé ijà náà.

7 Níbẹ̀ ni a gbé pa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó ṣubú lọ́jọ́ náà, àní ẹgbàáwá ènìyàn.

8 Ogun náà sì fọ́n káàkiri lórí gbogbo ilẹ̀ náà: igbó náà sì pa ọ̀pọ̀ ènìyàn ju èyí tí idà pa lọ lọ́jọ́ náà.

Jóábù Sì Kọlu Ábúsálómù.

9 Ábúsálómù sì pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Ábúsálómù sì gun orí ìbaka kan, ìbaka náà sì gba abẹ́ ẹ̀ka ńlá igi óákù kan tí ó tóbi lọ, orí rẹ̀ sì kọ́ igi óákù náà òun sì rọ̀ sókè ní agbede-méjì ọ̀run àti ilẹ̀; ìbaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sì lọ kúrò.

10 Ọkùnrin kan sì rí i, ó sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi rí Ábúsálómù so rọ̀ láàrin igi óákù kan.”

11 Jóábù sì wí fún ọkùnrin náà tí ó sọ fún un pé, “Sá wò ó, ìwọ rí i, èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi lù ú bolẹ̀ níbẹ̀? Èmi ìbá sì fún ọ ní ṣékélì fàdákà mẹ́wàá, àti àmùrè kan.”

12 Ọkùnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Ábíṣáì, àti Ítaì, pé, ‘Ẹ kíyèsí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù.’

13 Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ èmi ìbá ṣe sí ara mi: nítorí pé kò sí ọ̀ràn kan tí ó pamọ́ fún ọba, ìwọ tìkárarẹ̀ ìbá sì kọjú ìjà sí mi pẹ̀lú.”

14 Jóábù sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Ábúsálómù ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láàyè ní agbede-méjì igi óákù náà.

15 Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Jóábù sì yí Ábúsálómù ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á,

16 Jóábù sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Ísírẹ́lì: nítorí Jóábù ti pe àwọn ènìyàn náà padà.

17 Wọ́n sì gbé Ábúsálómù, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Ísírẹ́lì sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀.

18 Ábúsálómù ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ̀n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní àfonífojì ọba: nítorí tí ó wí pé, Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí: òun sì pe ọ̀wọ̀n náà nípa orúkọ rẹ̀: a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Ábúsálómù.

Dáfídì Ṣọ̀fọ̀.

19 Áhímásì ọmọ Sádókù sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìhìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀ta rẹ̀.”

20 Jóábù sì wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò mù ìhìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ijọ́ mìíràn: ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìhìn kan lọ, nítorí tí ọmọ Ọba ṣe aláìsí.”

21 Jóábù sì wí fún Kúṣì pé, “Lọ, kí ìwọ ro ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Kúṣì sì wólẹ̀ fún Jóábù ó sì sáré.

22 Áhímásì ọmọ Sádókù sì tún wí fún Jóábù pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tẹ Kúṣì lẹ́yìn.”Jóábù sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìhìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.”

23 Ó sì wí pé, “Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré.” Ó sì wí fún un pé, “Sáré!” Áhímásì sì sáré ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì sáré kọjá Kúṣì.

24 Dáfídì sì jókòó lẹ́nu odì láàrin ìlẹ̀kùn méjì: Álóre sì gòkè òrùlé bodè lórí odi, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wò, wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.

25 Álóre náà sì kígbe, ó sì wí fún ọba.Ọba sì wí pé, “Bí ó bá ṣe òun nìkan ni, ìhìn rere ń bẹ lẹ́nu rẹ̀.” Òun sì ń súnmọ́ tòsí.

26 Álóre náà sì rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré: Alóre sì kọ sí ẹni tí ń ṣọ́ bodè, ó sì wí pe, “Wò ó, ọkùnrin kan ń sáré òun nìkan.”Ọba sì wí pé, “Èyí náà pẹ̀lú ń mú ìhìn rere wá.”

27 Álóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáre ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Áhímásì ọmọ Sádókù.”Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìhìn rere wá!”

28 Áhímásì sì dé, ó sì wí fún ọba pé, “Àlàáfíà!” Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí Olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́.”

29 Ọba sì béèrè pé, “Àlàáfíà ha wà fún Ábúsálómù, ọmọdékùnrin náà bí?”Áhímásì sì dáhùn pé, “Nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀.”

30 Ọba sì wí fún un pé, “Yípadà kí o sì dúró nìhìn-ín.” Òun sì yípadà, ó sì dúró jẹ́ẹ́.

31 Sì wò ó, Kúṣì sì wí pé, “Ìhìnrere fún Olúwa mi ọba: nítorí tí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ lónìí lára gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ.”

32 Ọba sì bi Kúṣì pé, “Àlàáfíà kọ́ Ábúsálómù ọ̀dọ́mọdékùnrin náà wá bí?”Kúṣì sì dáhùn pe, “Kí àwọn ọ̀ta Olúwa mi ọba, àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ ní ibi, rí bí ọ̀dọ́mọdékùnrin náà.”

33 Ọba sì kẹ́dùn púpọ̀ ó sì gòkè lọ, sí yàrá tí ó wà lórí òkè ibodè, ó sì sunkún; bayìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, “Ọmọ mi Ábúsálómù! Ọmọ mi! Ọmọ mí Ábúsálómù! Áì! Ìbáṣepé èmi ni ó kú ní ipò rẹ̀! Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24