2 Sámúẹ́lì 12:16-22 BMY

16 Dáfídì sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dáfídì sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dúbúlẹ̀ lorí ilé ni orú náà.

17 Àwọn àgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.

18 Ní ijọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní ìṣẹ́ tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”

19 Nígbà tí Dáfídì sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dáfídì sì kìyésí i, pé ọmọ náà kú: Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?”Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”

20 Dáfídì sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin: ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì bèèrè, wọ́n sì gbé òunjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.

21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí lèyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láàyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sunkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”

22 Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sunkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’