27 Jóábù sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rábà jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olomi.
28 Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má báà gba ìlú náà kí a má baà pè é ní orúkọ mi.”
29 Dáfídì sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rábà, ó sì bá a jà, ó sì gbà á.
30 Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ talẹ́ńtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dáfídì lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀.
31 Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtùlẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe: bẹ́ ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ámónì. Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jérúsálẹ́mù.