2 Sámúẹ́lì 12:5-11 BMY

5 Ìbínú Dáfídì sì fàru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Nátanì pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè: ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkán yìí, kíkú ni yóò kú.

6 Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rinmẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”

7 Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èmi fi ọ́ jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù.

8 Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Ísírẹ́lì àti ti Júdà fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ ẹ̀ lọ.

9 Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gan ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Ùráyà ará Hítì, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.

10 Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúró ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Úráyà ará Hítì láti ṣe aya rẹ.’

11 “Bàyìí ni Olúwa wí, Kíyèsí i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrun yìí.