1 Jóábù ọmọ Sérúíà sì kíyèsí i, pé ọkàn ọba sì fà sí Ábúsálómù.
2 Jóábù sì ránṣẹ́ sí Tekóà, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀.
3 Kí o sì tọ ọba wá, kí o sọ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.” Jóábù sì fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu.
4 Nígbà tí obìnrin àrá Tékóà sì ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún ọba, ó wólẹ, ó dojúbolẹ̀, o sí bu ọlá fún un, o sì wí pé, “Ọba, gbà mi.”
5 Ọba sì bi í léèrè pé, “Kin ni o ṣe ọ́?”Òun sì dáhùn wí pé, “Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú.
6 Ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á.