2 Sámúẹ́lì 14:17-23 BMY

17 “Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba Olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú; nítorí bí ańgẹ́lì Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú: Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

18 Ọba sì dàhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, “Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́.”Obìnrin náà wí pé, “Jẹ́ kí Olúwa mi ọba má a wí?”

19 Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Jóábù kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?”Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láàyè, Olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí Olúwa mi ọba ti wí: nítorí pé Jóábù ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu.

20 Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Jóábù ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: Olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ańgẹ́lì Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.”

21 Ọba sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Ábúsálómù padà wá.”

22 Jóábù sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Jóábù sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, Olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.”

23 Jóábù sì dìde, ó sì lọ sí Géṣúrì, ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jérúsálẹ́mù.