2 Sámúẹ́lì 15:2-8 BMY

2 Ábúsálómù sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apákan ọ̀nà ẹnu ibodé: bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá.”

3 Ábúsálómù yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ sá dára, ó sì tọ́: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.”

4 Ábúsálómù a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan báà lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”

5 Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ ọn láti tẹ́ribá fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dì í mú, a sì fí ẹnu kò ó lẹ́nú.

6 Irú ìwà bàyìí ni Ábúsálómù sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sọ́dọ̀ rẹ̀.

7 Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Ábúsálómù sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hébírónì.

8 Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Géṣúrì ní Síríà pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jérúsálẹ́mù, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”