6 Irú ìwà bàyìí ni Ábúsálómù sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sọ́dọ̀ rẹ̀.
7 Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Ábúsálómù sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hébírónì.
8 Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Géṣúrì ní Síríà pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jérúsálẹ́mù, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”
9 Ọba sì wí fún un pé, “Má a lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hébúrónì.
10 Ṣùgbọ́n Ábúsálómù rán àmì sáàrin gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ábúsálómù jọba ní Hébúrónì.’ ”
11 Igba ọkùnrin sì bá Ábúsálómù ti Jérúsálẹ́mù jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkankan.
12 Ábúsálómù sì ránṣẹ́ pe Áhítófélì ará Gílónì, ìgbìmọ̀ Dáfídì, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Gílónì, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Ábúsálómù.