2 Sámúẹ́lì 20:6-12 BMY

6 Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, “Nísinsinyìí Ṣébè ọmọ Bíkírì yóò ṣe wá ní ibi ju ti Ábúsálómù lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má baà rí ìlú olódì wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.”

7 Àwọn ọmọkùnrin Jóábù sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára: wọ́n sì ti Jérúsálẹ́mù jáde lọ, láti lépa Ṣábà ọmọ Bíkírì.

8 Nígbà tí wọ́n dé ibi òkútà ńlá tí ó wà ní Gíbíónì, Ámásà sì ṣáájú wọn, Jóábù sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.

9 Jóábù sì bi Ámásà léèrè pé, “Ara rẹ kò le bí, ìwọ arákùnrin mi?” Jóábù sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Ámásà ní irungbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

10 Ṣùgbọ́n Ámásà kò sì kíyèsí idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Jóábù: bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́: ó sì kú. Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì.

11 Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Jóábù sì dúró tì í, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Jóábù? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dáfídì, kí ó máa tọ Jóábù lẹ́yìn.”

12 Ámásà sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì ríi pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú ìgbẹ́, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró.