13 Nípaṣẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ẹ̀yín-iná ràn.
14 Olúwa sán ààrá láti ọ̀run wá,ọ̀gá ogo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.
15 Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.
16 Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,nípa ìbáwí Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.
17 “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
19 Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi:ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀hìntì mi.