16 Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,nípa ìbáwí Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.
17 “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
19 Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi:ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀hìntì mi.
20 Ó sì mú mi wá sí àyè ńlá:ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.
21 “Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.
22 Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́,èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.