31 “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dán wò.Òun sì niaṣà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
32 Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.
33 Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.
34 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín;ó sì mú mi dúró ní ibi gígá mi.
35 Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà;tóbẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.
36 Ìwọ sì ti fún mi ní àsàìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.
37 Ìwọ sì fi àyè ńlá sí abẹ́ ìṣísẹ̀ mi;tóbẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.