5 “Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
6 Ọ̀já isà-òkú yí mi káàkiri;ìkẹ́kùn ikú dojú kọ mí.
7 Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa,èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi.Ó sí gbóhùn mi láti tẹ́ḿpìlì rẹ̀igbe mí wọ etí rẹ̀.
8 “Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì,ó sì mì, nítorí tí ó bínú.
9 Èéfín sì jáde láti ihò-imú rẹ̀ wá;iná láti ẹnu rẹ̀ wá,ó sì ń jónirun, ẹ̀yín sì ń ràn nípasẹ rẹ̀.
10 Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.
11 Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò:a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.