12 Ábínérì sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dáfídì nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Ísírẹ́lì tọ̀ ọ́ wá.”
13 Òun sì wí pé, “Ó dárá, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn: ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.”
14 Dáfídì sì rán àwọn ìránṣẹ sí Iṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù pé, “Fi Míkálì obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rún atoro àwọn Fílístínì fẹ́.”
15 Íṣíbóṣétì sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Fálítíélì ọmọ Láíṣì.
16 Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sunkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Báhúrímù Ábínérì sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà.
17 Ábínérì sì bá àwọn àgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dáfídì ní ìgbà àtijọ́, láti jọba lórí yín.
18 Ǹjẹ́, ẹ ṣe: nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dáfídì pé, ‘Láti ọwọ́ Dáfídì ìránṣẹ mi lémi ó gba Isíraẹ́lì ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀taa wọn.’ ”