13 Dáfídì sì ní òkìkí gidigidi nígbà tí ó padà wá ilé láti ibi pípa àwọn ará Síríà ní àfonífojì iyọ̀, àwọn tí o pa jẹ́ ẹgbaàsán ènìyàn.
14 Ó sì fi àwọn ológun sí Édómù; àti ní gbogbo Édómù yíká ni òun sì fi ológun sí, gbogbo àwọn tí ó wà ní Édómù sì wá sin Dáfídì, Olúwa sì fún Dáfídì ní ìṣẹgún níbikíbi tí ó ń lọ.
15 Dáfídì sì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì; Dáfídì sì ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
16 Jóábù ọmọ Sérúyà ni ó sì ń ṣe olórí ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì sì ń ṣe akọ̀wé.
17 Sádókù ọmọ Áhítúbì, àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì, ni àwọn àlùfáà; Sérúyà a sì máa ṣe akọ̀wé.
18 Bénáyà ọmọ Jéhóíádà ni ó sì ń ṣe olórí àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì; àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ aláṣẹ.