Dáníẹ́lì 12:4-10 BMY

4 Ṣùgbọ́n ìwọ Dáníẹ́lì, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”

5 Nígbà náà, ni èmi Dáníẹ́lì, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá ọ̀hún etí i bèbè.

6 Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

7 Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátapáta, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

8 Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo bèèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

9 Ó sì dáhùn pé, “Má a lọ ní ọ̀nà rẹ, Dáníẹ́lì nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dìí di ìgbà ìkẹyìn.

10 Ọ̀pọ́lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láì lábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búrurú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.