35 Mósè kò sì lè wọ inú Àgọ́ àjọ, nítorí àwọ́ọ́sánmọ̀ wà lórí rẹ, ògo Olúwa sì ti kún inú Àgọ́ náà.
36 Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbàkugbà tí a ba ti fa ikuuku àwọ̀ọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí Àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ;
37 ṣùgbọ́n tí àwọ̀ọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè.
38 Nítorí náà àwọ̀ọsánmọ̀ Olúwa wà lórí Àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọ̀ọsánmọ̀ ní òru, ní ojú gbogbo ilé Ísírẹ́lì ní gbogbo ìrìnàjò wọn.