1 Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ṣérísésì fún Ésítà ayaba ní ilée Hámánì, ọ̀ta àwọn Júù. Módékáì sì wá síwájú ọba, nítorí Ẹ́sítà ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba.
2 Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ọ Hámánì ó sì fi fún Módékáì, Ẹ́sítà sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olóórí ilée Hámánì.
3 Ẹ́sítà sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hámánì ará Ágágì, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù.
4 Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Ẹ́sítà ó sì dìde, ó dúró níwájúu rẹ̀.