5 Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kóòríra wọn.
6 Ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin run
7 Wọ́n sì tún pa parisánídátà, Dálífónì, Ásípátà,
8 Pórátà, Ádálíyà, Árídátà,
9 Parimásítà, Áríṣáyì, Árídáyì àti Fáíṣátà,
10 Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hámánì, ọmọ Hámédátà, ọ̀ta àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.
11 Ní ọjọ́ náà gan-an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà wá fún ọba.