1 Ìpín fún ẹ̀yà Júdà, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbégbé Édómù, títí dé ihà Síní ní òpin ìhà gúsù.
2 Ààlà wọn ní ìhà gúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúsù Òkun Iyọ̀,
3 Ó sì lọ sí gúsù Sikopioni Pasi lọ títi dé Sínì àti sí iwájú ìhà gúsù Kadesi Báníyà. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hésórónì lọ sí Ádárì, ó sì tún yípo yíká lọ sí Kákà.
4 Ó tún kọjá lọ sí Ásímónì, ó sì papọ̀ mọ́ Wádì ti Éjíbítì, ó parí sí òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúsù.
5 Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jọ́dánì.Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jọ́dánì,
6 ààlà náà sì tún dé Bẹti-Hógílà, ó sì lọ sí ìhà àríwá Bẹti-Árábà. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bóhánì ti ọmọ Rúbẹ́nì.