4 Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì.
5 Ìyòókù àwọn ọmọ Kóhátì ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù, Dánì àti ìdajì Mánásè.
6 Àwọn ẹ̀yà Gásónì ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara ẹ̀yà Ísákárì, Áṣíérì, Náfitalì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè ní Básánì.
7 Àwọn ọmọ Mérárì ní agbo ilé, agbo ilé ni wọ́n fún ní ìlú méjìlá láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Sébúlónì.
8 Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tutù fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Móse.
9 Láti ara ẹ̀yà Júdà àti ẹ̀yà Síméónì ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí,
10 (Ilú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Árónì tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kóhátì tí í ṣe ọmọ Léfì, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ ti wọn).