Nehemáyà 1:4-10 BMY

4 Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì ṣunkún. Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run.

5 Nígbà náà ni mo wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́.

6 Jẹ́ kí etíì rẹ kí ó ṣi sílẹ̀, kí ojúù rẹ kí ó sì sí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Ísírẹ́lì àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.

7 Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ mọ́.

8 “Rántí ìlànà tí o fún Móṣè ìránṣẹ́ rẹ, wí pé, ‘Bí ìwọ bá jẹ́ aláìṣòótọ́, èmi yóò fọ́n-ọn yín ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè.

9 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tílẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi.’

10 “Àwọn ni ìránṣẹ́ rẹ àti ènìyàn rẹ àwọn tí ìwọ rà padà pẹ̀lú agbára ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára ńlá rẹ.