1 Ní oṣù Níṣánì (oṣù kẹrin) ní ogún ọdún ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún-un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, Ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájúu rẹ̀.
2 Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn”Ẹ̀rù bà mí gidigidi,
3 Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! È é ṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?”
4 Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run,
5 mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Júdà ní bi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.”
6 Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan.