Nehemáyà 3:10-16 BMY

10 Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jédáyà ọmọ Hárúmáfì tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hátúsì ọmọ Háṣábínéjà sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ.

11 Málíkíjà ọmọ Hárímù àti Háṣúbù ọmọ Páhátì—Móábù tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti Ilé-ìṣọ́ Ìléru.

12 Ṣálúmù ọmọ Hálọ́ésì, alákóṣo ìdajì agbégbé Jérúsálẹ́mù tún ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀

13 Ibodè Àfonífojì ni Hánúnì àti àwọn ará Ṣánóà tún mọ. Wọ́n tún-un kọ́ wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ide rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún-ún kan ìgbọ̀nwọ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn.

14 Ẹnu ìbodè Ààtàn ni Málíkíjà ọmọ Rákábù, alákóṣo agbégbé Bẹti-Hákérémù tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìde rẹ̀ sí ààyè wọn.

15 Ẹnu Ìbodè Oríṣun ni Ṣálúnì ọmọ Kólí-Hóṣì, alákóṣo agbégbé Mísípà tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdáiùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi Adágún Ṣílóámù mọ, ní ẹ̀gbẹ́ Ọgbà Ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dáfídì.

16 Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemáyà ọmọ Áṣíbúkù, alákóṣo ìdajì agbégbé Bétí Ṣúrì ṣe àtúnmọ dé ibì ọ̀ọ́kan ibojì Dáfídì, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára.