5 Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájúú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé.
6 Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajìi gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lúu gbogbo ọkàn an wọn.
7 Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì, Tóbíyà, àwọn ará Árábù, ará Ámónì, àti àwọn ènìyàn Áṣídódì gbọ́ pé àtúnṣe odi Jérúsálẹ́mù ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi.
8 Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jérúsálẹ́mù jà àti láti dìde wàhálà sí í.
9 Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí.
10 Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Júdà wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.”
11 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀ta wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárin wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.”