5 Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà:
6 Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì ti kó ní ìgbékùn (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà, olúkúlùkù sí ìlúu rẹ̀.
64 Àwọn wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í nibẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́;
66 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n péjọ pọ̀ jẹ́ ẹgbàámọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360)
67 yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tàdínlẹ́gbaàrin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245).
68 Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736): ìbáákà wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245);
69 Ràkunmí wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rinlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6720).