1 Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá níṣinṣin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà já sí asán.
2 “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ire-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?”
3 Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀,—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.
4 Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀.
5 Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn.
6 Mo gbé adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà.
7 Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní agbo àgùntàn ju ẹnikẹ́ni ní Jérúsálẹ́mù lọ.