Oníwàásù 5 BMY

Dídúró Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run

1 Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti se ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.

2 Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹmá sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́runỌlọ́run ń bẹ ní ọ̀runÌwọ sì wà ní ayé,nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n

3 Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìtọ́jú púpọ̀ wàbẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.

4 Nígbà tí ó bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pé ní mímú ṣẹ kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ.

5 Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ.

6 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé-ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́?

7 Aṣán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Aṣán Ni Ọrọ̀ Jẹ́

8 Bí o bá rí talákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú títì, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dùú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lá bẹ́ rẹ̀ lójú ni, ṣìbẹ́ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì.

9 Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.

10 Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùnpẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún-un.

11 Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ síináà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ síiÈrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí oní nǹkanbí kò se pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rírí wọn?

12 Oorun alágbàṣe a máa dùn,yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀kì í jẹ́ kí ó ṣùn rárá.

13 Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùnọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun oní nǹkan.

14 Tàbí ọrọ̀ tí ó ṣọnù nípa àìrí ojúrere,nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrinkò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún-un.

15 Ìhòòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúròkò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.

16 Ohun búburú gbáà ni eléyìí pàápàá:Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọkí wá ni èrè tí ó jẹnígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?

17 Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ọ rẹ̀,pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.

18 Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀ nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún-un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí.

19 Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún-un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ̀—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.

20 Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ́kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12