Oníwàásù 1 BMY

Aṣán Ni Ohun Ayé

1 Ọ̀rọ̀ Oníwàásù, ọmọ Dáfídì, ọba Jérúsálẹ́mù:

2 “Aṣán! Aṣán!”ni oníwàásù wí pé“Aṣán pátapáta!Gbogbo rẹ̀ aṣán ni”

3 Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?

4 Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,síbẹ̀ ayé dúró títí láé.

5 Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,ó sì sáré padà síbi tí ó tí yọ.

6 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ihá gúṣù,Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.

7 Gbogbo odò ń sàn sí inú òkunsíbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún.níbi tí àwọn odò ti wá,níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí

8 Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá,ju èyí tí ẹnu le è ṣọojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ẹ lọ́rùn,bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.

9 Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìnòun ni a ó tún máa ṣe padàkò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.

10 Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è ṣọ wí pé,“Wòó! Ohun tuntun ni èyí”?Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́Ó ti wà ṣáájú tiwa.

11 Kò sí ìrántí ohun ìṣáájúbẹ́ẹ̀ ni ìrantí kì yóò sí fúnohun ìkẹyìn tí ń bọ̀lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.

Aṣán Ni Ọgbọ́n Ènìyàn

12 Èmi, Oníwàásù ti jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù rí.

13 Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn:

14 Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

15 Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́,ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.

16 Mo rò nínú ara mi, “Wòó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóṣo Jérúsálẹ́mù síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.”

17 Nígbà náà ni mo fi ara jìn láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti àgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

18 Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá,bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12