Oníwàásù 6 BMY

1 Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn.

2 Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ohun ìní àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohun kóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́ ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfàní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Aṣán ni èyí, àrùn búburú gbáà ni.

3 Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rún ọmọ kí ó sì wà láàyè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣíbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láàyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun-ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo ṣọ wí pé àbíkú ọmọ ṣàn jù ú lọ.

4 Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ farapamọ́ sí.

5 Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìṣinmi ju ti okùnrin náà lọ.

6 Kó dà, bí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun-ìní rẹ̀. Kìí ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?

7 Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ niṣíbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí

8 Kí ni àǹfàní tí ọlọgbọ́n ènìyàn nílórí aṣiwèrè?Kí ni èrè talákà ènìyànnípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tó kù?

9 Ohun tí ojú rí sànju ìfẹnúwákiri lọAṣán ni eléyìí pẹ̀lúó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

10 Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mímọ̀;kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadìpẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jùú lọ

11 Ọ̀rọ̀ púpọ̀,kì í ní ìtumọ̀èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?

12 Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti aṣán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? kò sí!

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12