Oníwàásù 7 BMY

Ọgbọ́n

1 Orúkọ rere ṣàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ

2 Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ju ibi àṣènítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyànkí alààyè ní èyí ní ọkàn.

3 Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọÓ le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le

4 Ọkàn ọlọgbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.

5 Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.

6 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkòni ẹ̀rín òmùgọ̀,Aṣán sì ni eléyìí pẹ̀lú.

7 Ìrẹ́jẹ a máa ṣọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.

8 Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,ṣùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.

9 Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹnítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.

10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti bèèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún-ìní jẹ́ ohun tí ó dáraó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.

12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbògẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbòṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyípé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá níi.

13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:“Ta ni ó le è toohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”

14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò óỌlọ́run tí ó dá èkínnínáà ni ó dá ìkejìnítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwáríohun kankan nípa ọjọ́ iwájúu rẹ̀.

15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:Ènìyàn olóòtìítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.

16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọtàbí ọlọ́gbọ́n jùlọkí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?

17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrèÈéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé

18 Ó dára láti mú ọ̀kankí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.

19 Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbáraju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú

20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyétí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.

21 Má ṣe kíyè sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.

22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹpé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmìíràn.

23 Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọgbọ́n”ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.

24 Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?

25 Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀,láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́nàti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwàbúburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.

26 Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọobìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkútétí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.

27 Oníwàásù wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.

28 Nígbà tí mo sì ń wá a kiriṣùgbọ́n tí n kò rí ìmo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrin ẹgbẹ̀rúnṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,kankan kí ó dúró láàrin gbogbo wọn.

29 Eléyìí nìkan ni mo tíì rí:Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12