Oníwàásù 10 BMY

1 Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún ìpara ní òórùn burúkú,bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.

2 Ọkàn ọlọgbọ́n a máa sí sí ohun tí ó tọ̀nà,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.

3 Kó dà bí ó ti ṣe ń rìn láàrin ọ̀nà,òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́na sì máa fi han gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.

4 Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,ma ṣe fi àyè rẹ sílẹ̀;ìdákẹ́jẹ́jẹ́ le è tu àṣìṣe ńlá.

5 Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.

6 A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jù lọ,nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn àyè tí ó kéré jù lọ.

7 Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,nígbà tí ọmọ aládé ń fi ẹṣẹ̀ rìn bí ẹrú.

8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán-an.

9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pe òkúta lẹ́jọ́ le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì-igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.

10 Bí àáké bá kútí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́nyóò nílò agbára púpọ̀ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.

11 Bí ejò bá sán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

12 Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.

13 Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìṣínwín búburú.

14 Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ta ni ó le è ṣọ fún-un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?

15 Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá lágbarakò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìgboro.

16 Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìranṣẹ́ rẹ̀àti tí àwọn ọmọ aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.

17 Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmọ̀tí para.

18 Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, ilé a máa wú,bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.

19 Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àṣè fún,wáìnì a máa mú ayé dùn,ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun—gbogbo.

20 Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ìbùsùn rẹ,nítorí pé ẹyẹ ojú—ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12