1 Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olòtìítọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bó yá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun.
2 Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn ń pín—olótìítọ́ àti òsìkà, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rúbọ àti àwọn tí kò rúbọ.Bí ó ti wà pẹ̀lú ọkùnrin rerebẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúrabẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.
3 Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìṣínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láàyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú.
4 Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá ṣàn dáadáa ju òkú ẹkùn lọ!
5 Nítorí pé ẹni tí ó wà láàyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kúṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kanwọn kò ní èrè kankan mọ́,àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
6 Ìfẹ́ wọn, ìríra wọnàti ìlara wọn ti parẹ́:láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpínnínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.
7 Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú-dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìṣinyìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe.
8 Má a wọ aṣọ funfun nígbàkugbà kí o sì máa fi òróró yan oríìrẹ nígbà gbogbo.
9 Má a jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrun.
10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣeé pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú iṣà-òkú níbi tí ò ń lọ.
11 Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùnEré-ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yáratàbí ogun fún alágbárabẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́ntàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òyetàbí ojú rere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀;ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
12 Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé:Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburútàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùngẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibití ó ṣubú lù wọ́n láì rò tẹ́lẹ̀.
13 Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn:
14 Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yìí po, ó sì kọ́ ilé-ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì síi.
15 Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ ọlọgbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n-ọn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin talákà náà.
16 Nítorí náà mo ṣọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin talákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.
17 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọgbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmú ṣeju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.
18 Ọgbọ́n dára ju ohun—èlò ogun lọ,ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kan a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.