1 Mo sì tún wò ó, mo sì ri gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn:mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kòsì ní Olùtùnú kankan,agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lárawọn kò sì ní olùtùnú kankan.
2 Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kútí wọ́n sì ti lọ,ó ṣàn fún wọn ju àwọntí wọ́n sì wà láàyè lọ.
3 Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn juàwọn méjèèjì lọ:ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburútí ó ń lọ ní abẹ́ oòrun.
4 Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbáratagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
5 Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kòó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
6 Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́jẹ́jẹ́ pèlú wàhálà,àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.
7 Lẹ́ẹ̀kan síi mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:
8 Ọkùnrin kan dá wà,kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbíwàhálà rẹ̀ kò lópin,ṣíbẹ̀, ọ̀rọ̀ ohun ìní rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó bèèrè pé,“Nítorí ta ni mo ṣe ń ṣe wàhálà”“àti wí pé kí ni ìdí tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”Eléyìí náà aṣán niiṣẹ́ ìbànújẹ́ ni.
9 Ẹni méjì ṣàn ju ẹnìkan,nítorí wọ́n ní ààbò rere fún iṣẹ́ wọn:
10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fàá sókè,ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubútí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn-án lọ́wọ́!
11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá ṣùn pọ̀, wọn yóò móoru.Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
12 Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn-ún yàra fà já
13 Òtòsì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó ṣàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn,
14 Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde ìjọba, bí a tilẹ̀ bí i ní talákà ní ìjọba rẹ̀.
15 Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí.
16 Gbogbo àwọn tí ó wà ní wájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.