1 Àwọn ọ̀rọ̀ ti Lémúélì ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀, tí ó jẹ́ pé mọ̀mọ́ rẹ̀ ló kọ ọ́:
2 “Ìwọ ọmọ mi, ìwọ ọmọ inú mi,ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ̀ mi.
3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.
4 “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lémúélìkì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnìkì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle
5 Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wíkí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n
6 Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbéwáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora;
7 Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọnkí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
8 “Ṣọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fún ra wọnfún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun
9 sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbèjà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”
10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?Ó níye lórí ju iyùn lọ
11 ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ púpọ̀ nínú rẹ̀kò sì sí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibiní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13 Ó sa aṣọ irun àgùtàn olówùú àti ọ̀gbọ̀Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn
15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀.
16 Ó kíyèsí oko kan, ó sì rà á;nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin àjàrà rẹ̀
17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbáratagbáraApá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́
18 Ó ríi pé òwò òun péfìtílà rẹ̀ kì í sìí kú ní òru
19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú múó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú
20 ó la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn talákàó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
21 Nígbà tí òjò dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;ẹwu dáradára àti eléṣè é àlùkò ni aṣọ rẹ̀
23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibòde ìlúníbi tí ó ń jókòó láàrin àwọn àgbà ìlú
24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́nó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò
25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́nìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27 Ó ń bojú tó gbogbo ètò ilé rẹ̀kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkúnọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un
29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́láṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ”
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asánnítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn
31 sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí ikí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibòde ìlú.