1 Yíyan orúkọ rere ṣàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
2 Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọ pọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
3 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n níyà.
4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
5 Ègún àti ìdẹkun ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
6 Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
7 Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,ajigbésè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
8 Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká aṣán:ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
9 Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
10 Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
11 Ẹni tí ó fẹ́ ìwà-funfun ti àyà,tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
12 Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́,ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!Ó pa mí ní ìgboro!”
14 Ẹnu àwọn Àṣẹ́wó obìnrín, ihò jínjìn ni;ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
15 Àyà ọmọdé ni ìwà-wèrè dì sí;ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
16 Ẹni tó ń ni talákà lára láti ní ọrọ̀,tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
17 Dẹtí rẹ sílẹ̀,kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
18 Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;nígbà tí a sì pèṣè wọn tán ní ètè rẹ.
19 Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà níti Olúwa,èmi fi hàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
20 Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradárasí ọ níti ìmọ̀ràn àti níti ẹ̀kọ́,
21 Kí ó lè mú ọ mọ dídájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?
22 Má ṣe ja talákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ talákà:bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè:
23 Nítorí Olúwa yóò gbéjà wọn,yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
24 Má ṣe bá oníbìínu ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
25 Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀,ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
26 Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀wọ́,tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
27 Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi ṣan,nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹní rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
28 Má ṣe yẹ ààlà ilẹ ìgbàanì,tí àwọn baba rẹ ti pa.
29 Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.