1 Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nàní ìkòríta, ní ó dúró;
3 Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
4 Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
5 Ẹ̀yin aláìmọ́kan, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin aláìgbọ́n, ẹ gba òye.
6 Tẹ́tí, nítorí mo ní àwọn ohun iyebíye láti sọ;Mo ya ẹnu mi láti sọ àwọn ohun tí ó tọ̀nà,
7 Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,nítorí ètè mi kórìíra ibi.
8 Gbogbo ọrọ ẹnu mi ni ó tọ́,kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyídà níbẹ̀
9 Fún Olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11 Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù ìyùn lọ,kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fi wé e.
12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkóòríra ibimo kóríra ìgbéraga àti agídí,ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmimo ní òye àti agbára.
15 Nípaṣẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkósotí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ aládé ń ṣàkósoàti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn miàwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wàỌrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21 mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mimo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23 A ti yàn mí láti ayérayé,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24 Nígbà tí kò tíì sí òkun, ni a ti bí minígbà tí kò tíì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28 Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfuurufú lókètí ó sì fi oríṣun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹṣẹ̀,
29 Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi òkunkí omi má baà kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,mo ń yọ̀ nígbà gbobgbo níwájú rẹ̀
31 mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dámo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́
33 fetí sí ìtọ́ṣọ́nà mi kí o sì gbọ́n;má ṣe pa á tì sápá kan.
34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetí sílẹ̀ sí mi,tí ń sọ́nà ní ẹnu ọ̀nà mi lójoojúmọ́,tí ń dúró ní ẹnu ọ̀nà mi.
35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyèó sì rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.
36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ láragbogbo ẹni tí ó kórira mi fẹ́ ikú.”