1 Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetí sílẹ̀ kí o sì ní òye sí i
2 Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooroNítorí náà má ṣe kọ ìkọ́ni mi sílẹ̀
3 Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi
4 Ó kọ́ mi ó sì wí pé“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,pa òfin mí mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
5 Gba ọgbọ́n, gba òye,Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹṣẹ̀ kúrò nínú rẹ̀
6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojú tó ọ.
7 Ọgbọ́n ni ó ga jù; Nítorí náà gba ọgbọ́n.Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye
8 Gbé e ga, yóò sì gbé ọ gadìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
9 Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹyóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”
10 Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
11 Mo tọ́ ọ sọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́nmo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
12 Nígbà tí o rìn, ìgbẹ́sẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́nígbà tí o bá sáré, iwọ kì yóò kọsẹ̀.
13 Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;tọ́jú u rẹ̀ dáradára Nítorí òun ni ìyè rẹ.
14 Má ṣe gbé ẹṣẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburútàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
15 Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ
16 Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú
17 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búrurúwọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.
18 Ipa ọ̀nà Olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùntí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
19 ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
20 Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi
21 Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójúpa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;
22 Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọnàti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn
23 Ju gbogbo nǹkan tó kù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́Nítorí òun ni oríṣun ìyè,
24 mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìṣọkúṣọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
25 Jẹ́ kí ojú ù rẹ máa wo iwájú,jẹ́ kí ìwo ojú ù rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sáá.
26 Kíyèsí ìrìn ẹṣẹ̀ rẹsì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan
27 má ṣe yà sọ́tùn-ún tàbí ṣósìpa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.