1 Wọ̀nyí ni àwọn òwé mìíràn tí Sólómónì pa, tí àwọn ọkùnrin Hẹsikáyà ọba Júdà dà kọ.
2 Ògo Olúwa ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́;láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.
3 Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jìnbẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba.
4 Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákàohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà
5 mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọbaa ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípaṣẹ̀ òdodo.
6 Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba,má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrin àwọn ènìyàn pàtàkì
7 Ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síhìn ín”ju wí pé kí ó dójú tì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì.
8 Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rímá ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìnbí aládùúgbò rẹ bá dójú tì ọ́?
9 Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ,má ṣe tú àsírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,
10 àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójú tì ọ́orúkọ burúkú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.
11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹó dàbí èṣo wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
12 Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradárani ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.
13 Bí títutù òjò yìnyín ní àsíkò ìkórèni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn tí ó rán anó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú.
14 Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láì sí òjòni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.
15 Nípa ṣùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padàahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun.
16 Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nbabí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í.
17 Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbotàbí kí ó máa lọ ṣíbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.
18 Bí àdá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó múni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀.
19 Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹṣẹ̀ tí ó rọni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdàámú.
20 Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú,tàbí iyọ̀ tí a fi ra ojú egbò ọgbẹ́ tàbí bí ọtí kíkan tí a dà sórí sódàní ẹni tí ń kọ orin sí ọkàn tí ó bàjẹ́.
21 Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ;bí òrùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú.
22 Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọẹ̀san rẹ̀ fún ọ.
23 Bí afẹ́fẹ́ gúṣù ti í mú òjò wá,bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá.
24 Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùléju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.
25 Bí omi tútù sí ẹni tí òrùngbẹ ń gbẹni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn.
26 Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kanga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ni olódodo tí ó fi àyè gba ènìyàn búburú.
27 Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù,bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́nni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.