Òwe 30 BMY

1 Àwọn ọ̀rọ̀ Ágúrì ọmọ Jákè, ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Ítíélì, sí Ítíélì àti sí Úkálì:

2 “Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;N kò ní òye ènìyàn.

3 Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́ntàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì

4 Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?Sọ fún mi bí o bá mọ̀.

5 “Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;oun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn

6 Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.

7 “Ohun méjì ni mo ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa;má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú:

8 Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan,

9 Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹkí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’Tàbí kí ń di òtòsì kí ń sì jalèkí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.

10 “Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣẹ́ èpè lé ọ. Ìwọ yóò sì jìyà rẹ̀.

11 “Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọntí wọn kò sì ṣúre fún àwọn ìyá wọn:

12 Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọnṣíbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;

13 Àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo,tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.

14 Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idàÀwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹláti jẹ àwọn talákà run kúrò ní ilẹ̀ ayéàwọn aláìní kúrò láàrin àwọn ọmọ ènìyàn.

15 “Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì‘Múwá! Múwá!’ ní wọn ń ké.“Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé,mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó’:

16 Ibojì, inú tí ó yàgàn,ilẹ̀, tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé,àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’

17 “Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀,tí ó kẹ́gàn ìgbọràn sí ìyáẹyẹ àkálá ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́,igún yóò mú un jẹ.

18 “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,mẹ́rin tí kò yé mi:

19 Ipa idì ní òfuurufúipa ejò lórí àpátaipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami òkunàti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúndíá lọ́wọ́.

20 “Èyí ni ọ̀nà alágbérè obìnrinó jẹun o sì nu ẹnu rẹ̀ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.

21 “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ile ayé ti ń wárìrìlábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.

22 Ìránṣẹ́ tí ó di Ọbaaláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ́

23 Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24 “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyésíbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi;

25 Àwọn èrà jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní agbára díẹ̀síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò

26 Ehoro jẹ́ ẹ̀dá tí kò ní agbára púpọ̀ṣíbẹ̀ wọ́n ń ṣe ilé wọn sí ibi ihò àpáta;

27 Eṣú kò ní ọbaṣíbẹ̀ wọ́n ń jáde lọ papọ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

28 a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbáṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

29 “Àwọn ohun mẹ́ta ní n bẹ tí ń rìn rere,ohun mẹ́rin tí ń kọrí sí ibi rere,

30 Kìnnìún, alágbára láàrin ẹrankotí kì í sá fún ohunkóhun

31 Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ,àti ọba pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láyìíká rẹ̀.

32 “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!

33 Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wátí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jádebẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31