Òwe 10 BMY

Àwọn Òwe Sólómónì

1 Àwọn òwe Sólómónì:Ọlọgbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùnṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

2 Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrèṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

3 Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa Olódodoṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

4 Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà,ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀.

5 Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

6 Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodoṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.

7 Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkúnṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

8 Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

9 Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwuṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

10 Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkànAláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

11 Ẹnu Olódodo jẹ́ oríṣun ìyèṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

12 Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

13 Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóyeṣùgbọ́n kùmọ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

14 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

15 Ọrọ̀ àwọn Olódodo ni ìlú olódi wọn,ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

16 Èrè Olódodo ń mú ìyè wá fún wọnṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

17 Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hànṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn sìnà.

18 Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ẹni tí ó sì ń báni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.

19 Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kùṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

20 Ètè Olódodo jẹ́ àṣàyan fàdákàṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn buburú kò níye lórí.

21 Ètè Olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.

22 Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá,kì í sìí fi ìdàámú sí i.

23 Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburúṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.

24 Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

25 Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

26 Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojúbẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

27 Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

28 Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.

29 Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún Olódodo,ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.

30 A kì yóò fa Olódodo tu láéláéṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

31 Ẹnu Olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.

32 Ètè Olódodo mọ ohun tí ó tọ́,ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31