Òwe 23 BMY

Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ Ohun Àdídùn

1 Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,kíyèsí ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.

2 Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.

3 Má ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀:nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

4 Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:síwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.

5 Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́-apá fún ara rẹ̀,ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.

6 Má ṣe jẹ oúnjẹ olójú búburú,bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀.

7 Nítorí pé bí ẹni tí ń sírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:“Má a jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.

8 Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.

9 Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè (òmùgọ̀);nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.

10 Má ṣe sí ààlà àtijọ́ kúrò;má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.

11 Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.

12 Fi àyà sí ẹ̀kọ́,àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

13 Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé,nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.

14 Bí ìwọ fi pàṣán nà án,ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run-àpáàdì.

Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Fún Ọmọ Rere

15 Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n,ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.

16 Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.

17 Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa,ní ọjọ́ gbogbo.

18 Nítorí pé ìkẹyìn ń bẹ nítòótọ́;ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.

19 Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.

20 Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;

21 Nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di talákà;ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.

22 Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó

23 Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́, àti òye.

24 Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.

25 Jẹ́ kí bàbá rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.

26 Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi,kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú-dídùn sí ọ̀nà mi.

27 Nítorí pé panṣágà-obìnrin ọ̀gbun jínjìn ni;àti àjèjì-obìnrin kànga híhá ni.

28 Òun á sì ba ní bùba bí olè,a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.

29 Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́?Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni aṣọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?

30 Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí-wáìnì;àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.

31 Ìwọ má ṣe wò ọtí-wáìnì nígbà tí ó pọ́n,nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

32 Níkẹyìn òun á bunisán bí ejò,a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

33 Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ àyídáyidà.

34 Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárin òkun,tàbí ẹni tí ó dúbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.

35 Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí;wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀:nígbàwo ni èmi ó jí?Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31