1 Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkànṢùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
2 Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dà bí i pé ó dára lójú ara rẹ̀Ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
3 Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
4 Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́Kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
5 Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
6 Nípaṣẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀nípaṣẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.
7 Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn-án bá a gbé ní àlàáfíà.
8 Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodoju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú.
9 Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
10 Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa inú síiẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ gbé ẹ̀bi fún ara rẹ̀.
11 Òdiwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
12 Àwọn ọba kórìírà ìwà àìtọ́nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.
13 Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣòótọ́ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ ṣe iyebíye sí wọn.
14 Ìrànṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.
15 Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;ojú rere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
16 Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọàti láti yan òye dípò o fàdákà!
17 Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.
18 Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú,
19 ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrin àwọn olùpọ́njújù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.
20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ire,ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.
21 Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóyeọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
22 Òye jẹ́ oríṣun ìyè fún àwọn tí ó ní i,ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
23 Ọkàn ọlọgbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú.
24 Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyinó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
25 Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyànṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
26 Ìfẹ́-àti-jẹun alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún unnítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ ni.
27 Ènìyàn búburú ń pèteọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
28 Aláyìídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn níyà.
29 Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
30 Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
31 Ewú orí jẹ́ ògoìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀.
32 Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ.
33 A ṣẹ́ kèké dàsí ìṣẹ́po aṣọ,ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.