Òwe 18 BMY

1 Ènìyàn tí kò báni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.

2 Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òyeṣùgbọn ó ní inú dídùn sí ṣíṣọ èrò tirẹ̀.

3 Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dénígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.

4 Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jínjìnṣùgbọ́n oríṣun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń ṣàn.

5 Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúṣáájú fún ènìyàn búburútàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.

6 Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.

7 Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ọkàn rẹ̀.

8 Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùnwọ́n ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara.

9 Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.

10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.

11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọnwọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

12 Sáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéragaṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

13 Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́òun náà ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.

14 Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsànṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.

15 Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.

16 Ẹ̀bùn máa ń sí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùna sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.

17 Ẹni tí ó kọ́kọ́ rojọ́ máa ń dàbí i pé ó jàretítí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àsírí gbogbo.

18 Ìbò dídì máa ń parí ìjàa sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.

19 Arákùnrin tí a ṣẹ̀ ṣòroó yípadà ju ìlú olódi lọ,ìjà sì dàbí ibodè ìlú olódi ńlá tí a ṣe.

20 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.

21 Ahọ́n ni agbára ìyè àti ikú,àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹẹ́.

22 Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,Ó sì gba ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa.

23 Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,Ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.

24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parunṢùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó sún mọ́ ni tímọ́ tímọ́ ju arákùnrin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31