1 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
2 Nítorí wọn yóò fún ọ ní ọjọ́ gígùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdúnkí ó sì mú ọ̀rọ̀ wá fún ọ.
3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláéso wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,kọ wọ́n sí síléètì àyà rẹ.
4 Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojú rere àti orúkọ rerení ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹmá ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;
6 Jẹ́wọ́ rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹyóò sì ṣe àkóso ọ̀nà rẹ.
7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹbẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
8 Èyí yóò mú ìlera fún ara à rẹàti okun fún àwọn egungun rẹ.
9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,pẹ̀lú àkọ́so oko ò rẹ
10 Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnyaàgbá rẹ yóò kún à kún wọ́ sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
11 Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwamá si ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12 Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wíbí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,ẹni tí ó tún ní òye síi
14 Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;kò sí ohunkohun tí a lè fi wé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìtura,òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbàá;àwọn tí ó bá sì dìí mú yóò rí ìbùkún gbà.
19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipòo wọn;
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní ìyà,àwọ̀sánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
21 Ọmọ mi pa ìdájọ́ tí ó yè kooro mọ́ àti ìmọ̀yàtọ̀,má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn
22 wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọàti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ
23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìṣéwu,ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀;
24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rùnígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀
25 má ṣe bẹ̀rù ìdàámú òjijìtàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú
26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹkì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.
27 Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí,nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,“Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; ó fún ọ lọ́lá”nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
30 Má ṣe fẹ̀ṣùn kan ènìyàn láì-ní-ìdínígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgantàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀,
32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyìídáyidàṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo
34 Ó fi àwọn oníyẹ̀yẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́Ṣùgbọ́n ó fi oore ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀
35 ọlọ́gbọ́n jogún iyìṢùgbọ́n àwọn aláìgbọ́n ni ó dójú tì.