Òwe 13 BMY

1 Ọlọ́gbọ́n ọmọ pa àṣẹ baba rẹ̀ mọ́ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò fetí sí ìbáwí.

2 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn àwọn ohun rereṣùgbọ́n, aláìsòótọ́ ní ìfẹ́ ọkàn láti inú ìwà ipá.

3 Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù-gbàù yóò parun.

4 Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkankan,ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

5 Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

6 Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòótọ́ inú,ṣùgbọ́n ìwà búburú sí ẹlẹ́ṣẹ̀ nípò.

7 Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkankanẹlòmííràn díbọ́n bí i talákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

8 Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ṣùgbọ́n talákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

9 Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,ṣùgbọ́n àtùpà ènìyàn búburú ni a pa kú.

10 Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ niṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11 Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi.

12 Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14 Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹkùn ikú.

15 Òye pípé ń mú ni rí ojú rereṢùgbọ́n ọ̀nà aláìsòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16 Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

17 Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdàámúṣùgbọ́n aṣojú olóòtọ́ mú ìwòsàn wá.

18 Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di talákà yóò sì rí ìtìjú,ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

19 Ìfẹ́ tí a múṣẹ dùnmọ́ ọkànṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

20 Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

21 Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

22 Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

23 Ilẹ̀ ẹ talákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko wáṣùgbọ́n àìsòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

24 Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa báa wí.

25 Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùnṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31