1 Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwíyóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
2 Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.
3 Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́
4 Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládúgbò rẹ̀ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.
6 Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹkùn rẹ̀ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.
7 Olódodo ń ṣaápọn nípa ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn tálákà,ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó kan ènìyàn búburú nínú irú rẹ̀.
8 Àwọn Ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.
9 Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́naláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.
10 Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kòrí ẹni-dídúró-ṣinṣinwọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.
11 Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹ̀nú rẹ̀ bínúṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.
12 Bí olórí bá fetí sí irọ́,gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.
13 Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.
14 Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ talákà pẹ̀lú òtítọ́ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdí múlẹ̀ nígbà gbogbo.
15 Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́nṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójú ti ìyá rẹ̀.
16 Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ṣùgbọ́n Olódodo yóò rí ìṣubú wọn.
17 Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíàyóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.
18 Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà.Ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfín mọ́.
19 A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi-ara-síi.
20 Njẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.
21 Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeréyóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.
22 Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,Onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.
23 Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.
24 Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn.
25 Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹkùnṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.
26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóṣo,ṣùgbọ́n láti ọdọ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.
27 Olódodo kórìíra àwọn aláìsòótọ́:ènìyàn búburú kórìíra olódodo.