1 Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
2 tí o tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́ntí o sì fi ọkàn rẹ sí òye,
3 bí ìwọ sì pè fún ojú inú rẹ rírantí o sì kígbe sókè fún òye
4 bí ìwọ bá wá ṣàfẹ́rì rẹ̀ bí i fàdákàtí o sì wa kiri bí i fún ohun iyebíye tó fara sin.
5 Nígbà náà ni òye ẹ̀rù Olúwa yóò yé ọ,tí ó sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
6 Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá
7 Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,Òun ni aṣà fún àwọn tí ń rìn déédé,
8 ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.
9 Nígbà náà ni òye ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì dára,tí ó dára yóò yẹ́ ọ—gbogbo ọ̀nà dídara.
10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ
11 Ara (ikú) sísọ ni yóò dáàbò bò ọÒye yóò sì pa ọ́ mọ́.
12 Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
13 tí ó kúrò ní ọ̀nà tààràláti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
14 tí ó ní inú dídùn sí ibi ṣíṣetí ó sì ń yayọ̀ nínú àyídáyidà ibi,
15 ọ̀nà àwọn tí ó ṣe pálapàlatí wọ́n sì jẹ́ alérekérekè ní ọ̀nà wọn.
16 Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àgbèrè Obìnrinlọ́wọ́ aya oníwàkúwà àti àwọn ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀,
17 tí ó ti fi ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run.
18 Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikúọ̀nà rẹ̀ sì lọ sí ibi ẹ̀mí àwọn òkú.
19 Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padàtàbí tí ó rí ipa ọ̀nà ìyè.
20 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rerekí o sì rìn ní ọ̀nà àwọn Olódodo
21 Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náààwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà lórí rẹ̀
22 ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náàa ó sì ya àwọn aláìsòótọ́ kúrò lórí rẹ̀.