1 Bí òjò dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórèọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn.
2 Bí ológoṣẹ́ tí ń sí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rá bàbàÈpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpèÈpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè.
3 Lagbà fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.
4 Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.
5 Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
6 Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipáni kí a ránṣẹ́ nípaṣẹ̀ aṣiwèrè.
7 Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodironi òwe lẹ́nu àṣiwèrè.
8 Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títani fífún aláìgbọ́n ní ọlá.
9 Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtíni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.
10 Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kanni ẹni tí ó gba aṣiwèrè síṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
11 Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
12 Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀?Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.
13 Ọ̀lẹ wí pé: “Kìnnìún wà lójú ọ̀nàkìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”
14 Bí ilẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.
15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ,ó lẹ débi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
16 Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọgbọ́n.
17 Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí múni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.
18 Bí i asínwín ti ń juọfà àti ọfà tí ń ṣekú pani
19 ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹtí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.”
20 Láìsí igi, iná yóò kúláì sí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.
21 Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná,bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.
22 Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlèwọn a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara.
23 Bí èédú lára ìkòkò, bẹ́ẹ̀ niẹnu tí ó mú ṣáṣá pẹ̀lú ọkàn búburú.
24 Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àsírí ara rẹ̀ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.
25 Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.
26 Ìkóríra rẹ le è farasin nípa ẹ̀tànṣùgbọ́n àsírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.
27 Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.Bí ẹnikan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.
28 Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pani run.